Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu Ọmọọba Suleiman Abubakar, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sai Kayi ati Olumide Daniel Ibitoye gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ oṣelu ni ẹkun aarin gbungbun (Special Assistant Political for Central Senatorial District).
Oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni gomina kede awọn mejeeji ọhun ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita fawọn akọroyin.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti jẹ ka mọ pe lẹyin bi oṣu meloo kan ti wọn yan Malaamu AbdulKareem Yusuf Danhawa, fun ẹkun aarin gbungbun Ariwa, ni wọn yan awọn meji yii.
No comments:
Post a Comment