Àgba olórin Jùjú nnì, Dayọ̀ Kújọrẹ̀ jáde láyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 11, 2022

Àgba olórin Jùjú nnì, Dayọ̀ Kújọrẹ̀ jáde láyé


Gbajugbaja olorin Juju nni, Dayọ Kujọrẹ ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelọgọta, lọjọ Aje, Mọnde, ana.

Ogbontarigi ni Dayọ Kujọrẹ nidi iṣẹ orin, to si pẹlu awọn to sọ orin Juju di irọrun fawọn to tun bẹrẹ, paapaa awọn to n bọ lẹyin.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii le fidi iku to pa ọkunrin naa mulẹ, ṣugbọn ti a gbọ pe aisan rampẹ kan lo ṣeku pa a.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 1958 ni wọn bi oludasilẹ 'Sọkọ Extra' naa lagboole Rọbiyan to wa ni Igbore nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. Inu ijọ awọn alawọ dudu, iyẹn African Church ni wọn bi Kujọrẹ si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI