A rò bí ogun máa ṣẹlẹ̀ l'Ọ́ṣun ni, ṣùgbọ́n... - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 19, 2022

A rò bí ogun máa ṣẹlẹ̀ l'Ọ́ṣun ni, ṣùgbọ́n... - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣalaye pe inu oun dun si bawọn eeyan ṣe jade lọpọ yanturu lati dibo yan ẹni ti yoo jade du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ọṣun.

AbdulRazaq to jẹ alakoso eto idibo abẹle fun ẹgbẹ APC, eyi to waye lonii kaakiri ipinlẹ Ọṣun gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn oludije patapata, to si loun nifẹẹ si bi wọn ṣe gba alaafia laaye.

O tun sọ pe oriṣiriṣi iroyin tawọn n gbọ kaakiri inu iwe iroyin ati ori ayelujara ni pe ogun nla ni yoo ṣẹlẹ lonii, ṣugbọn to pada ja si ọpẹ fun gbogbo eeyan.

Awọn oludije to dupẹ lọwọ wọn ni Gomina Gboyega Oyetọla; ọmọ ile igbimọ aṣofin kekere nilu Abuja tẹlẹri, Ọnọrebu Lasun Yusuf, ati akọwe ijọba ipinlẹ ọhun tẹlẹri, Mọṣhood Adeoti.

Nibẹ lo ti sọ pe bi awọn eeyan ṣe jade lati dibo, ti fi han daju pe ẹgbẹ naa ṣi wa ni digbi, paapaa ni imurasilẹ fun ipo oṣelu.

O wa jẹ ko di mimọ pe ko si magomago tabi awuruju kankan ninu eto idibo ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI