Kubura Alaragbo, gbajumọ olorin Waka jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 20, 2022

Kubura Alaragbo, gbajumọ olorin Waka jade laye


Iroyin to tẹ wa lọwọ ni yajoyajo bayii ni pe gbajugbaja onkọrin Waka nni, Alaaja Kuburat Alaragbo ti jade laye.

Ọkan lara awọn pedepede nipinlẹ Ogun, Akinyẹmi Ọlatoye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Alawiye Fẹdireṣan lo gbe iroyin iku Alaragbo sori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ laipẹ yii, to si tun ṣalaye ọrọ ti wọn jọ sọ gbẹyin ko to ku.

Ọmọ bibi ilu Iporo nipinlẹ Ogun naa la gbọ pe o n ṣe ipalẹmọ ikojade ati ipolongo kasẹẹti rẹ tuntun lọwọ ni, ko to di pe ẹlẹmin gba a.

Ẹkunrẹrẹ bi obinrin naa ṣe ku n bọ laipẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI