AbdulRazaq gbawọn aṣoju ile-ẹjọ ECOWAS lalejo nibi aṣalẹ ounjẹ ara ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 27, 2022

AbdulRazaq gbawọn aṣoju ile-ẹjọ ECOWAS lalejo nibi aṣalẹ ounjẹ ara ọtọ


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lalẹ ọjọ Ẹti, tii ṣe Furaidee ti gba awọn aṣoju ile-ẹjọ ECOWAS lalejo nibi apejẹ aṣalẹ ounjẹ ara-ọtọ to waye nilu Ilọrin, ipinlẹ naa.

Nibẹ ni wọn ti gbe oriyin fun Gomina lori iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati jẹ ki wọn yan ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi ibi ti wọn yoo fi ile-ẹjọ naa kalẹ si.
 
Ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe igbimọ ẹlẹni mẹẹdogun naa wọlu Ilọrin fun ipolongo ọlọsẹ kan gbako lati jẹ kawọn eeyan, paapaa awọn oṣiṣẹ mọ pataki ile-ẹjọ naa, ati ohun ti wọn yoo maa ṣe nibẹ.

Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq sọ pe "Ninu esi ti mo ti ri gba nipa ipolongo ti ẹ ti ṣe, gbogbo rẹ ni mo ri i pe o dara. Oriṣiriṣi iroyin lo ti wa lati ọdọ yin si ọdọ wa, ati lati ọdọ wa si ọdọ yin, ti a si ti mọ ọpọ ẹjọ ti yoo maa waye nile-ẹjọ yii."
 
Lara awọn to tun wa nibi apejẹ naa ni Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Yakubu Salihu Danladi; Adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Durosinlọhun Kawu; Grand Kadi fidihẹ tile ẹjọ koẹmilọrun Shariah, Onidajọ Abdullateef Kamaldeen; Kọmiṣanna fọrọ eto idajọ, Onidajọ Salman Jawondo (SAN).
 
Awọn miran ni: Oludamọran pataki lori ọrọ ofin, Murtala Sambo; Alaga ati akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Ọmọọba Sunday Fagbemi ati Mustapha Isowo; alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ naa, Abdulganiyu Bello; atawọn mi in.
 
Igbakeji alaga ile-ẹjọ ECOWAS, Onidajọ Gberi-be Quattara la gbọ pe o lewaju igbimọ naa lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI