Àgbà òṣèré tíátà, Tàfá Olóyèdé ti kú o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 1, 2022

Àgbà òṣèré tíátà, Tàfá Olóyèdé ti kú o


Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ti sọ pe agba oṣere tiata nni, Tafa Oloyede ti jade laye, to si n ṣe ọpọ awọn eeyan ni kayeefi nla.

Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun naa la gbọ pe o bẹrẹ iṣẹ tiata lọdun 1974, to si ti kopa ribiribi nidi iṣẹ tiata ọhun.

Abẹ agba oṣere nni, to ti filẹ ṣe aṣọbora, Oyin Adejobi ni Tafa Oloyede ti bẹrẹ iṣẹ tiata, to si ti kopa ninu sinima bii 'Jaiyesimi', 'Ayanmọ', 'Ekurọ Ọlọja', 'Orogun', ati 'Akanji Oniposi' to gbe e jade.

Aarọ oni, Tusidee, ọjọ kin-ni-in, oṣu keji, ọdun 2022 ni Oloyede ku nile ẹ to wa lagbegbe Arowomọlẹ, Kajọla nilu Oṣogbo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI