Awọn araalu gbe akanṣe eto adura kalẹ fun Gomina AbdulRazaq lati pada sipo lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 17, 2022

Awọn araalu gbe akanṣe eto adura kalẹ fun Gomina AbdulRazaq lati pada sipo lẹẹkeji


Wọn ni yinniyinni, k'ẹni o le ṣe, lo n mu ki ori ẹni to n ṣe rere wu. Wọnyi gan-an lọrọ to lọ ni ibamu pẹlu bi awọn araalu Ajikọbi ṣe gbe akanṣe eto adura kalẹ fun Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lati pada sipo naa lẹẹkeji.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ara agbegbe wọọdu Ajikọbi to wa lẹkun Iwọ Oorun Ilorin ni wọn gbe eto akanṣe adura yii kalẹ lati fi bẹ Olodumare, ko le jẹ ki AbdulRazaq pada sipo gomina.
 
A gbọ pe wọn tun fẹẹ lo akanṣe eto adura yii lati fi mọ riri bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe da wọn lọla, to si fi ipo kọmiṣanna ta wọn lọrẹ lẹkun naa.
 
Ojọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu keji ti a wa yii ni akanṣe eto adura ọhun fẹẹ waye ni wọọdu Ajikọbi to wa ni ikorita Abeemi. Agogo mẹwaa owurọ ni wọn yoo bẹrẹ lakọtun, ti wọn si n bẹ awọn eeyan lati darapọ mọ wọn.
 
Ninu lẹta to tẹ AWIKONKO lọwọ, eyi ti Onimọ-ẹrọ Baba Hammed, to jẹ akọwe wọọdu Ajikọbi fii sita lo ti jẹ ka mọ pe ipa rere ti Gomina wọn n ko kaakiri ipinlẹ naa lawọn gbọdọ fi imọriri wọn han, nipa ṣiṣe agbatẹru bi yoo tun ṣe pada sipo ọhun lẹẹkeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI