Ijọba Kwara tun ṣe iranlọwọ nla fawọn ile-ẹkọ kaakiri ilu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 17, 2022

Ijọba Kwara tun ṣe iranlọwọ nla fawọn ile-ẹkọ kaakiri ilu


Beeyan ba wa nipinlẹ Kwara l'Ọjọru, Wẹsidee ana, to ri ipa rere ti Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq tun ko lẹka eto ẹkọ, yoo mọ pe idagbasọke alailẹgbẹ tun ti wọlu naa.
 
Ọjọ naa ni ijọba Kwara bẹrẹ pinpin awọn ohun elo ileewe fun gbogbo awọn ile-ẹkọ to wa nipinlẹ naa, eyi ti yoo jẹ ki iṣẹ rọrun fun wọn lai si idaduro.

Nibi eto ọhun ti igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayode Alabi, ti ṣoju fun Gomina AbdulRazaq lo ti jẹ ko di mimọ pe ọrọ eto ẹkọ to jẹ ijọba logun lo mu ki wọn dide iranlọwọ lati pin awọn ohun elo amuṣẹya fun wọn.
 
Lara awọn ohun elo tijọba pin naa ni awọn ohun elo ere idaraya bi aṣọ ati bata, ile-ẹọ alagbeeka mẹwaa, ibusun, kọmputa ati oriṣiṣiri miran. Gbogbo ile-ẹkọ ijọba to wa kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun nipinlẹ Kwara ni wọn jẹ anfaani nla yii.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI