Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati agbegbe nipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Abọsede Ọlaitan Buraimọh ti sọ pe gbogbo awọn to n da ilẹ ati idọti sibi ti ko yẹ kaakiri ipinlẹ naa ni yoo bẹrẹ sii ti ika abamọ bọ ẹnu nigba tọwọ palaba wọn ba bẹrẹ sii segi.
Ọnọrebu Buraimọh sọ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ojubọrọ ko ṣee gba ọmọ lọwọ ekurọ, afi ki wọn kan an nipa fun gbogbo araalu, paapaa awọn to n huwa ibajẹ nipinlẹ naa.
Lakooko to n ṣabẹwo si bawọn eeyan ṣe n tẹle ilana ati ofin dida ilẹ ati idọti nu, Ọnọrebu Buraimọh sọ pe alaigbọran lo pọ ju ninu awọn olugbe ipinlẹ naa, ti awọn si gbọdọ jẹ ki wọn bẹrẹ sii jiya ẹṣẹ wọn lakọtun.
O ni ipinlẹ ọhun ko nii laju silẹ mọ lati maa wo awọn to n da idọti nu sibi ti ko yẹ, paapaa kaakiri opopona ati iwaju ile onile, to si ni eto ati ilana lawọn eeyan gbọdọ maa tẹle bayii.
No comments:
Post a Comment