O ma se o! Mọto akero jabọ lori afara l'Abẹokuta, eeyan meji lo ku loju ẹsẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 2, 2022

O ma se o! Mọto akero jabọ lori afara l'Abẹokuta, eeyan meji lo ku loju ẹsẹ


Ko din ni eeyan meji ti wọn ti jẹ Ọlọrun nipe lonii, Ọjọru, Wẹsidee, nibi ijamba mọto to waye lagbegbe Olomore, nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Ori afara Olomore nijọba ibilẹ Abẹokuta North nijamba naa ti waye laago mẹjọ kọja ogun iṣẹju, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Awọn meji ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn jade laye loju ẹsẹ, ko to di pe awọn ẹlẹyinju aanu, atawọn oṣiṣẹ eleto aabo oju popona debẹ lati doola ẹmi awọn to kagbako ijamba yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI