Ayé ò! Àwọn adigunjalè kọlu mọ́tò agbówórìn n'Íbàdàn, wọ́n pa ọlọ́pàá méjì danù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 10, 2022

Ayé ò! Àwọn adigunjalè kọlu mọ́tò agbówórìn n'Íbàdàn, wọ́n pa ọlọ́pàá méjì danù


Ko din ni ọlọpaa meji ọtọọtọ ti wọn lawọn adigunjale pa danu lọsan oni, Ọjọbọ, Tọside nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si tun gbe obitibiti owo salọ.

Mọto agboworin kan ti wọn n pe ni Bullion Van, eyi to n gbe owo lọ, pẹlu awọn ọlọpaa lẹyin la gbọ pe awọn adigunjale ọhun kọlu lagbegbe Idi Ape nigboro ilu Ibadan.

A gbọ pe ṣe ni wọn ṣina bolẹ fawọn ọlọpaa naa, ti ọrọ ai di boolọ o yago lọna.

Lara awọn araalu to wa lagbegbe yii fi ara kaaṣa ijamba naa, iyẹn lakoko ti ibọn n ro lakọ-lakọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI