Àṣírí tú! Bùkọ́lá Sàràkí fi dúkìá ìjọba Kwara yá owó lásìkò tó wà nípò gómìnà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 8, 2022

Àṣírí tú! Bùkọ́lá Sàràkí fi dúkìá ìjọba Kwara yá owó lásìkò tó wà nípò gómìnà


Wẹrẹ bayii ni aṣiri naa tu sita wi pe Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki fi dukia ijọba Kwara ya obitibiti owo lọwọ awọn ileeṣẹ kaakiri, iyẹn lakooko to wa lori ipo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa.

Lonii ni iroyin naa tẹ AWIKONKO lọwọ wi pe ajọ kan ti wọn pe ni Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON), ti gba dukia ti Sẹnetọ Bukọla Saraki fi duro lati fi ya owo.

A gbọ pe ṣe ni gbajigbaja oloṣelu naa ya owo nla yii lorukọ ileeṣẹ aladani kan ti wọn pe ni Shonga Farms Holding Nigeria Limited, eyi to wa nipinlẹ Kwara, to si jẹ pe dukia ijọba lo fi duro nigba naa.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI