Latigba ti wọn sọ pe obinrin ti ẹ n wo yii ti jade kuro nile, lati lọ silu Ẹdẹ ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi to wa titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
Temitọpẹ Abiọdun Omiṣina lorukọ obinrin naa. Ipinlẹ Eko lo si n gbe pẹlu ọkọ rẹ.
Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe Temitọpẹ sọ fun ọkọ rẹ wi pe oun fẹẹ lọ sile ẹkọ gbogboniṣe toun ti ṣetan nilu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun, lati lọ gba iwe ẹri oun.
Wọn ni igba to n padabọ lo pe ọkọ rẹ ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee wi pe oun ti n padabọ nile. O loun ṣẹṣẹ wọ mọto ilu Ẹko ni ni garaaji kan to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Igba naa ni wọn sọ pe wọn ti gburo rẹ mọ, ti ko si sẹni to le sọ pato ibi to wa. Iwadii ti wọn ṣe ni wọn ti ṣakiyesi pe obinrin naa de agbegbe Iyana Iyesi, Ọta, nipinlẹ Ogun.
Foonu rẹ ni wọn tọpinpin de agbegbe yii, ti wọn ko si rii mọ.
Gbogbo mọlẹbi ni wọn n wa obinrin yii, ti wọn si n bẹbẹ pe ki gbogbo ẹni to ba ṣalabapade rẹ tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
No comments:
Post a Comment