Nitori Aṣọ Adirẹ China: Awọn alaṣọ Adirẹ fẹẹ bẹ Liṣabi ati Oke Olumọ lọwẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 22, 2022

Nitori Aṣọ Adirẹ China: Awọn alaṣọ Adirẹ fẹẹ bẹ Liṣabi ati Oke Olumọ lọwẹ

Alaaja Kẹmi Oloyede

Kii ṣe asọdun tabi awijare rara wi pe ilu Ẹgba ni Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni orirun aṣọ Adirẹ, eyi ti awọn oloyinbo tun n pe ni Kampala kaakiri agbaye.

Pupọ awọn eeyan si ni wọn fẹran rẹ, koda, ti awọn ilu kan bii Oṣogbo naa si ti bẹrẹ sii sọ pe awọn lawọn ni Aṣọ Adirẹ.
 
Bawọn eeyan ṣe fẹran rẹ to, lo jẹ ki orileede China dide lati bẹrẹ sii ṣe ayederu aṣọ naa, fun tita kaakiri agbaye. Kii ṣe agbaye nikan ni wọn n ta awọn aṣọ yii si, wọn tun n ta a silu Ẹgba, nibi to jẹ orirun aṣọ ọhun.

Ọpọ awọn eeyan si ni wọn n ra ayederu aṣọ Adirẹ ti orileede China n ko wọle yii, paapaa bo tun ṣe jẹ pe owo pọọku ni wọn n ta a.
 
Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ bu ẹnu atẹ lu aṣọ Adirẹ ti China, to si ni bi ẹni to fọwọ ọla gba ilu Ẹgba leti ni iwa ti China hu, nitori pe awọn ko lagbara to wọn lati doju ija kọ wọn.
 
"Lotitọ ni pe awọn ara China ti n ṣe aṣọ Adirẹ, ti wọn si ti n ko o wa si Naijiria. Gbogbo nnkan to ba n jade kuro China, wọn maa n fun wọn lowo ti wọn lọhun, to ba wa wu wọn, wọn le ko fun wọn nibi lọfẹẹ, iyẹn lo n jẹ kawọn eeyan wọn maa ṣiṣẹ, ijọba lo maa faragba eyi to ba jẹ pe wọn ti padanu.
 
"Awa ko le ba wọn figagbaga lori aṣọ ti wọn n gbe wọle wa fun wa, ṣugbọn a ni nnkan ti wọn ko ni, gbogbo ọna ni aṣọ ti wa fi dara ju ti wọn lọ. Ko ṣee fi we ara wọn, gbogbo ẹnu ni mo le fi sọ ọ wi pe aṣọ wọn ko le duro lẹgbẹ aṣọ ti wa, nitori pe awa la ni nnkan wa.
 
"Awọn Iyalọja lo le sọrọ lori rẹ pupọ, lori ọna ti wọn n gba lati rii pe aṣọ Adirẹ ti wa ko parun, nitori pe awọn ni wọn wa nidi ẹ. Ọlọrun a fun wa ṣe, ẹ jẹ ka maa mu aṣọ Adirẹ nibi inawo ti a n ṣe."
 
Iyalọja ilu Ẹgba, Oloye Alaaja Oluwakẹmi Oloyede nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin fun ti ayẹyẹ ọdun Liṣabi t'ọdun 2022, ẹlẹẹkẹtadinlogoji iru ẹ, eyi to waye ni Aafin Alakẹ tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, o sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ fawọn wi pe awọn China ti ko mọ bi aṣọ naa ṣe bẹrẹ ti fẹẹ ba a jẹ mọ wọn lọwọ
 
"Wọn ko ri oogun ẹ ṣe. Gbogbo agbaye ni wọn gba wi pe awa Ẹgba la ni aṣọ Adirẹ, ko si kuro lọwọ ibi ti awọn iya-n-la wa fọwọ si, ṣugbọn awọn China n wa ra awọn aṣọ yẹn lọwọ wa nibi ni. Awọn nnkan ti wọn si fi n ṣe aṣọ ti wọn la ti rii pe awọn nnkan naa le ba eeyan ni awọ {Body} jẹ ni. Aṣọ yọlọyọlọ ni, ko le duro ni ara bii ojulowo aṣọ Adirẹ ti wa.
 
"Awa ko ni agbara kankan ti a le fi doju ija kọ China, ṣugbọn a n fi ẹjọ wọn sun Ọlọrun. Gbogbo awa ti a n ṣe aṣọ Adirẹ lati panupọ nibi ipade ti a ṣe wi pe ni ọjọ ayẹyẹ Lisabi tọdun yii, a n lọ si ẹsẹ Olumọ, lati lọ fi ẹjọ wọn sun awọn alalẹ.
 
"Iṣẹ awọn alalẹ la n ṣe, awọn si ni wọn le gba wa. Awa naa si ti n jẹ ko ye gbogbo awọn to n ra awọn aṣọ yii wi pe wọn gbọdọ maa wo iyatọ laaarin ojulowo aṣọ Adirẹ si ayederu ti wọn n ko wọle fun wa. Aṣọ China ko buyi to lawujọ nitori pe kii duro ni ara eeyan, a si ti n sọ fun gbogbo awọn to n ra a wi pe awọn China maa n ba eeyan lara jẹ, nitori pe a ko mọ nnkan ti wọn fi ṣe e.
 
"A ti sọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe ra a mọ nitori pe ko ṣee wọ, ko dara rara. Adirẹ ti wa gan-an lo ni alubarika ninu. Ibi ti a ṣi ba a de ni pe a n lọ fi ẹjọ wọn sun awọn alalẹ ni igbo Liṣabi ati ọdọ Olumọ, ki wọn gba wa lọwọ awọn China."
 
Iyalode Alaba Lawson ninu ọrọ tirẹ naa jẹ ko di mimọ pe:
 
Awa Chambers of Commerce, a ti gbe igbesẹ nipa awọn China, a ti jẹ ko ye wọn pe ki wọn dawọ duro lai jẹ pe wọn gba aṣẹ lọwọ ijọba apapọ. Ṣugbọn awọn eeyan wa gan-an ni wọn lọ ra awọn aṣọ wọnyi. Ohun to ba jẹ ogun ibi eeyan, a ko gbọdọ fi tọrẹ mọ, bi awọn eeyan wa ko ba ra a lọwọ wọn mọ, eyi to ṣe pataki, awọn naa ko ni ri ohunkohun gbe jade.
 
A ṣi ni anfaani wi pe ẹyin baba wa ṣi maa da si i, nitori pe awọn aṣọ ti a fi n ṣe aṣọ Adirẹ, ṣe lawọn kọsitọọmu n da wọn duro, ti wọn si n gba lọwọ wọn. Aimọye igba ni mo ti gba aṣọ lọwọ kọsitọọmu lai jẹ ki wọn san owo. A ni lati maa fi ye awọn eeyan wi pe aṣọ China kii ṣe ohun teeyan le maa ra. Awọn aṣọ yii maa n gun eeyan lara, ko si dara fun wiwọ.
 
Kii ṣe awọn China nikan ni wọn n sọ pe awọn lawọn ni aṣọ Adirẹ, awọn Oṣogbo gan-an sọ pe ọdọ wọn ni aṣọ Adirẹ ti bẹrẹ, ṣugbọn irọ nla patapata ni, Ẹgba lo ni i, awa naa gbọdọ gbe aṣa wa larugẹ, ki awọn eeyan le ba wa gbe e larugẹ, Chambers of Commerce n ṣiṣẹ takuntakun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI