Ajọ to n ṣakoso aisan ati ajakalẹ arun lorileede Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control (NCDC) ti sọ pe eeyan ti ko din ni ogoji ni aisan aṣepani Iba Lassa ṣeku pa loṣu kin-in-ni, ọdun ti a wa yii.
Ọjọ Aiku, Sannde, ana ni ajọ NCDC gbe ọrọ naa sita fun araye, wi pe ogoji eeyan lawọn ni akọsilẹ rẹ ti aisan naa ṣeku pa.
Ajọ naa tẹsiwaju pe eeyan mọkanla-le-n'igba (211) lawọn to kagbako aisan yii, ninu awọn to din diẹ ni ẹgbẹrun kan awọn ti wọn fura si (981).
Bẹẹ ni wọn jẹ ko di mimọ pe eeyan kọọkan nipinlẹ mẹrinla lo ni arun yii, ati pe ijọba ibilẹ mẹtalelogoji lawọn ti ṣawari gbogbo wọn.
Ipinlẹ Ondo ni wọn ti ri ida mejilelọgọrin, awọn yooku ni wọn ri nipinlẹ Ẹdo ati Bauchi
No comments:
Post a Comment