Ẹ gbọ ohun ti Sadio Manẹ ba Abou Gabal, aṣọle Egypt sọ lori papa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 7, 2022

Ẹ gbọ ohun ti Sadio Manẹ ba Abou Gabal, aṣọle Egypt sọ lori papa


Ṣe lọrọ naa dabi asasi nigba ti agbọọlu orileede Senegal nni, Sadio Manẹ gba bọọlu si aṣọle orileede Egypt, Abou Gabal (Gabaski) lọwọ nibi afaani ti wọn ni lati gba bọọlu wọle, iyẹn Penalty.
 
Mohamed Salah ti Egypt lo sare lọ ba Gabal wi pe apa ọtun ni Sadio Manẹ maa gba bọọlu ọhun si, nitori naa, ibẹ ni ko fo si lati mu un.
 

Salah sọ fun Gabal pe awọn jọ n gba bọọlu ni kilọọbu kan naa ni, fun idi eyi, oun mọ ibi to n gba bọọlu rẹ si.
 
Nibi ti Salah ti n tu aṣiri yii ni Manẹ ti sare lọ sibẹ lati sọ fun Gabal wi pe ko ma ṣe da Salah lohun, nitori pe ọtọ ni ibi toun yoo gba bọọlu oun si.
 
Si iyalẹnu, ibi ti Salah sọ fun aṣọle wọn, Gabal wi pe Salah yoo gba bọọlu ọhun lo gba a si, ti aṣọle naa si mu, bi ẹni mu adiẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI