Pasitọ Adebọye sọ wahala ti yoo koju awọn agbebọn lẹkun Ariwa Ila-Oorun Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 13, 2022

Pasitọ Adebọye sọ wahala ti yoo koju awọn agbebọn lẹkun Ariwa Ila-Oorun Naijiria


Alakoso agba fun ṣọọṣi Ridiimu lagbaye, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti sọ asọtẹlẹ ibanujẹ si gbogbo awọn agbebọn aṣekupani to wa lẹkun Ariwa Ila Oorun (North-East) orileede yii wi pe opin yoo de ba wọn laipẹ.
 
Ori ikanni ayelujara ti fesibuuku ni Pasitọ Adeboye ti sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ana lẹyin akanṣe eto ‘Light Up Nigeria’ to waye nipinlẹ Gombe.

Wọn gbe eto yii kalẹ lara-ọtọ fun ti ipalẹmọ ayẹyẹ ọgọrin ọdun ti ojiṣẹ Ọlọrun naa fẹẹ ṣe laipẹ yii.
 
Ninu ọrọ rẹ, Pasitọ Adeboye sọ pe 
“Ogo Ọlọrun ni ẹkun Ariwa Ila-Oorun orileede Naijiria yii yoo pada wa nipa oore-ọfẹ Ọlọrun.
 
“Mo fi ipinlẹ Gombe ṣe atẹgun wi pe bi ina Ọlọrun ṣe sọkalẹ pẹlu agbara nla lakooko akanṣe eto @reach4christ, ina Ọlọrun yoo sọkalẹ sori gbogbo agbegbe ti idaamu wa lorileede wa Naijiria.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI