Wòlíì Ọládélé, Genesis Global ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí àrà-ọ̀tọ̀ fún Kasnaty, gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní ṣọọṣi rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 13, 2022

Wòlíì Ọládélé, Genesis Global ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí àrà-ọ̀tọ̀ fún Kasnaty, gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní ṣọọṣi rẹ̀


Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Israel Ọladele Ogundipe lonii, ọjọ Aiku, Sannde ti fi ẹmi imoore rẹ han si ogbontarigi sọrọsọrọ ti aye n pokiki rẹ lakooko yii, Kọlawọle Atanda Adejojo ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar.

Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, iyẹn ọjọ kọkanla, oṣu keji ti a wa yii ni Kasnaty Sugar ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, ọdun marundinlaadọta ni ọkunrin naa pe bayii.

Nigba to n sọrọ, Wolii Genesis sọ pe oun ko gbọdọ ma ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi naa fun Kasnaty nitori pe oun ko le gbagbe oore nla ti ọkunrin naa ṣe foun, ati ipa to ko lakoko toun wa ninu ipenija.

O ni Kasnaty ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi foun lakoko toun n la awọn adojukọ kan kọja. O ni Kasnaty jọ oun loju pupọ, toun ko si le gbagbe titilai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI