Wahala Rọṣia ati Ukrain ko ba ma ṣẹlẹ kani wọn ko ṣe awuruju eto idibo US - Trump sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 27, 2022

Wahala Rọṣia ati Ukrain ko ba ma ṣẹlẹ kani wọn ko ṣe awuruju eto idibo US - Trump sọrọ


Aarẹ ilẹ Amẹrika ana, Donald Trump ti sọ pe kani ki i ṣe awuruju ti wọn ṣe lakoko idibo ilẹ Amẹrika lọdun 2020 ni, ikọlu to n waye laaarin ilẹ Ukraine ati Russia ko ba ma waye.
 
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Joe Biden ati NATO lori wahala ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ lorileede Ukraine lọwọlọwọ, to si ni bi wọn ṣe yi bio lati fi gbe Biden wọle ko bojumu.
 
Nibi eto ọlọdọọdun kan ti wọn pe ni Conservative Political Action Conference, eyi to waye ni Orlando, Florida ni Trump ti sọrọ yii.
 
O ni lara awon abuda ati ipenija ti Biden ni lo fa a ti wahala naa fi waye, to si gbe oriyin fun Aarẹ Vladimir Putin lori ọgbọn to n lo.
 
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe kani ki i ṣe pe wọn yi ibo ni, wahala yii ko nii ṣẹlẹ rara, nitori toun mọ ọna lati dẹkun rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI