Lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, Orímọlúsì tuntun gb'ọ̀pá àṣẹ n'Íjẹ̀bú Igbó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 27, 2022

Lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, Orímọlúsì tuntun gb'ọ̀pá àṣẹ n'Íjẹ̀bú Igbó


Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ awọn araalu Ijẹbu Igbo nipinlẹ Ogun, nigba ti Gomina Dapọ Abiọdun gbe ọpa aṣẹ fun Ọba Lawrence Jaiyeọba Adebajo gẹgẹ bi Orimọlusi tilu Ijẹbu Igbo tuntun.

Oni tii ṣe Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2022 ni Gomina Abiọdun gbe ọpa aṣẹ ati iwe aṣẹ gẹgẹ bi ọba tuntun le kabiyesi naa lọwọ.

AWIKONKO ri i gbọ pe latigba ti Orimọlusi ana waja lọdun mejidinlọgbọn sẹyin, wọn ko yan ẹlomiran lati rọpo rẹ.

Nigba to n sọrọ, Gomina Dapọ Abiọdun gba ọba tuntun lamọran lati lo ipo rẹ fi mu idagbasoke ati iṣọkan ba ilu naa, paapaa alaafia ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI