Kasnaty fi owó nlá tọrẹ lọ́jọ́ ìdúpẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 16, 2022

Kasnaty fi owó nlá tọrẹ lọ́jọ́ ìdúpẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ l'Ékòó


Ara-ọtọ lọjọ Aiku tii ṣe Sannde, to kọja yii gba yọ nigba ti gbajugbaja sọrọsọrọ agbaye nni, Kọlawọle Atanda Adejojo fi ẹbun obitibiti owo ta obinrin kan lọrẹ lati fi bẹrẹ ọja rẹ, ko le kuro lẹni to n tọrọ jẹ lawujọ.
 
Kii ṣe akọkọ ree ti Kọlawọlẹ Adejojo, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar yoo maa ṣe iranlọwọ fawọn alaini, paapaa bo ṣe n fi eto rẹ, 'Street Voices with Kasnaty' ṣe awọn eeyan loore, ṣugbọn eyii yatọ si bo ṣe maa n ṣe tẹlẹ.

Ṣọọṣi Ṣẹlẹ ti Wolii Israel Ọladele Ogundipe, iyẹn Genesis ni eto ọhun ti waye.
 
Obinrin ti Kasnaty fun ni ni owo yii, Arabinrin Juliet Okenare la gbọ pe sọrọsọrọ naa ti pe awọn ẹlẹyinju aanu kaakiri agbaye lati dide iranlọwọ fun un, ti a si gbọ pe owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (300,000) naira ni wọn da fun un, lati fi bẹrẹ okoowo.
 
A gbọ ep bi wọn ṣe ko owo yii fun Arabinrin Juliet, ko ri owo ọhun fi ṣe nnkan gidi, nitori pe gbogbo awọn ohun to maa n ṣe tẹlẹ, lo ti pa ti, ti ko si ṣe wọn mọ.
 
Nigba to n sọrọ lọjọ naa, Kasnaty Sugar jẹ ko ye wa pe ṣaaju koun to pade obinrin naa, o maa n gbadura loore-koore, to si maa n gba aawẹ, koda, to sọ pe o maa n riran. Ṣugbọn ni kete to sọ pe obinrin naa pade oun, toun si dide iranlọwọ fun un, ṣe lo pa Ọlọrun rẹ ti, ko si ṣe awọn nnkan to maa n ṣe mọ.
 
Eyi gan-an ni Kasnaty sọ pe o jẹ iṣoro ti ko fi ri owo naa lo bo ti tọ ati bo ti yẹ. O nigba toun rii pe obinrin naa ti pada sọdọ Ọlọrun rẹ, loun tun fi pinnu lati ṣe iranlọwọ miran fun un, gẹgẹ bi itọni Ọlọrun toun gba.
 
Nibẹ lo ti wa bẹbẹ pe ki ẹnikẹni ma ṣe pe oun lati maa beere fun iranlọwọ, nitori pe oun kii ṣe Ọlọrun, to si ni ẹni ti Ọlọrun ba ran oun si, loun maa n rin pade lati ṣe iranlọwọ fun wọn.
 
Bakan naa lo ṣalaye pe ọpọ awọn mọlẹbi oun lo wa ninu iṣẹ ati oṣi, ti wọn ko si ranṣẹ pe oun lati tọrọ owo lọwọ oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI