Aarẹ Buhari ṣe ikilọ nla fawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 13, 2022

Aarẹ Buhari ṣe ikilọ nla fawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC


Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lori wahala ti wọn n ba ara wọn fa, to si ni ki wọn gbajumọ idagbasoke ati iṣọkan ẹgbẹ naa.
 
Buhari ninu atẹjade to gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Graba Shehu lo ti sọ pe rọ wọn lati dẹkun awọn ọrọ kugbakugbe ti wọn n sọ si ara wọn.
 
O ni ki wọn gbajumọ ipade gbogboogbo ẹgbẹ wọn to n bọ laipẹ, iyẹn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta ti a wa yii, ki wọn si di ara wọn mu ṣinṣin.
 
Bakan naa lo sọ pe ki wọn wo awokọṣe bi ẹgbẹ oṣelu alatako nni, Peoples Democratic Party, PDP ṣe ṣubu, to fi jẹ kawọn rọwọ mu, ki wọn si ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ gẹgẹ bi ohun idanimọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI