Wọ́n ní MC Olúọmọ pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW bẹ̀rẹ iṣẹ́ padà láwọn garaaji l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 14, 2022

Wọ́n ní MC Olúọmọ pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW bẹ̀rẹ iṣẹ́ padà láwọn garaaji l'Ékòó


Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì lè fi ìdí ìròyìn náà múlẹ̀, ṣùgbọ́n iroyin tó tẹ wá lọ́wọ́ laipẹ yìí sọ pé alága ẹgbẹ́ awakọ tí NURTW, ẹka tí Ìpínlẹ̀ Èkó tí wọn yọ danu laipẹ yìí, Alaaji Musiliu Akinsanya tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ sì MC Olúọmọ tí pàṣẹ wí pé kí gbogbo àwọn alaga ẹgbẹ́ onimọto ọhun padà sẹnu iṣẹ lai fi àkókò ṣòfò. 

Nínú lẹta kan tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ laipẹ yìí, èyí tí MC Olúọmọ fúnra rẹ bù ọwọ lu fi ye wá pé ọkùnrin náà fẹ ki atunto wá nínú ẹgbẹ́ NURTW, pàápàá nipinlẹ Eko. 

MC Olúọmọ nínú lẹ́tà náà sọ pé kí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí, àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ náà má ṣe wo ojú àwọn ọlọ́pàá tí wọn wá káàkiri garaaji láti dá wọn lọ́wọ́ kọ lẹ́nu iṣẹ. 

Bákan náà ni wọn tún fi nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kan síta wí pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn pé, ìyẹn láti fi ẹjọ́ àwọn ọlọ́pàá tó bá fẹẹ di wọn lọ́wọ́ iṣẹ sún. 

Lẹta náà rèé:


Ṣáájú àkókò yìí là gbọ pé MC Olúọmọ tí pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ onimọto má ṣe lo tikẹẹti NURTW mọ, bí kò ṣe èyí tí ìjọba Èkó fi ọwọ sì. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI