Ajo 'Safe A Girl Initiative' gbé àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kalẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Luwasa l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 15, 2022

Ajo 'Safe A Girl Initiative' gbé àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kalẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Luwasa l'Ékòó


Ajọ kan to n ri sọrọ awọn obinrin, pàápàá àwọn ọmọbínrin, ìyẹn 'Save A Girl Initiative', lonii, ọjọ Ìṣẹgun, Tusidee, ọjọ keedogun, oṣù kẹta, ọdun 2022 gbé idanilẹkọọ ara-ọtọ kalẹ fún àwọn ọdọbínrin.

Gbogbo awọn akẹkọọbínrin ti ile ẹkọ girama Luwasa (Junior), eyi to wa lagbegbe Ijede niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko la gbọ pé wọn kopa nibi idanilẹkọọ naa.


Idanilẹkọọ ọhun ti wọn pe akori re ni “Pad A Girl: Cultivating a Healthy Lifestyle” la gbọ pé wọn gbé kalẹ pẹlu ajọṣepọ ìjọba ibilẹ idagbasoke Ijede, ìyẹn Ijede Local Council Development Area.

Nígbà to n soro nibi idanilẹkọọ naa, alakoso àjọ ọhun, Arabinrin Comfort Ọlafare sọ pé kii ṣe pé wọn déédéé gbe idanilẹkọọ yìí kalẹ, bi ko ṣe pé àwọn nilo lati jẹ ki awọn ọmọbinrin mọ nipa eto ilera wọn nipa ìbálòpọ̀.


“A ni oye nipa pataki ilera pàápàá fún àwọn ọmọbìnrin tó ṣẹṣẹ n dagba bọ. Idi ree ti a fi gbe eto yii kalẹ pẹlu ìpinnu àti afojusun 'Save A Girl Initiative' lati jẹ ki wọn rí ará wọn.

"Ọpọ nínú wọn ni wọn kò ní ẹkọ kikun, tó sì jẹ pé ṣe ni awọn miran ṣi ẹkọ gba, pàápàá nípa lílo paadi (sanitary pads), eyi ti ko yẹ kó lo ju wakati mẹjọ lara."


Alaga ẹgbẹ ìjọba ibilẹ idagbasoke, Ọnarebu Motunrayọ Gbadebọ-Alogba ninu ọrọ tirẹ ṣàlàyé pé ọmọbìnrin gbọdọ mú ilera ati alaafia ara rẹ lokukudun, pàápàá lakooko ti wọn ba n ṣe nnkan oṣù lọwọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI