Ojuṣe gbogbo wa ni lati ma jẹ ki aṣa ati iṣe wa lọ soko iparun – Gomina Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 17, 2022

Ojuṣe gbogbo wa ni lati ma jẹ ki aṣa ati iṣe wa lọ soko iparun – Gomina Abiọdun


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti jẹ ko di mimọ pe ojuṣe gbogbo ọmọ Yoruba ni lati gbe aṣa ati iṣe dide, ko si ma ba a lọ soko iparun titilai, fun idi eyi, o ni ki gbogbo obi ati alagbatọ ri i daju pe wọn n jẹ ki awọn ọmọ wọn sọ ede abinibi.

Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo sọrọ yii nibi idije ifigagbaga laaarin awọn akẹkọọ nipa fifi ede Ẹgba ṣe ohun ariyanjiyan ati orin kikọ, eyi ti Sẹnetọ to ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Sẹnetọ Lanre Tẹjuoṣo ṣagbatẹru ẹ nilu Abẹokuta.

Gbogbo awọn akẹkọọ ile ẹkọ to wa ni aaarin gbungbun ipinlẹ Ogun ni wọn kopa nibi idije ati ifigagbaga naa, eyi ti aṣkagba rẹ waye ninu gbọngan ayẹyẹ ti OOPL, to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.


Nigba to n gba ẹnu gomina ipinlẹ Ogun sọrọ, Ọmọwe Toyin Taiwo to jẹ alabojuto agba lẹka ọrọ aṣa ati irin ajo afẹ nipinlẹ naa sọ pe iwuri nla ni eto yii jẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe;
“Gẹgẹ bi akiyesi ti a ṣe, idije yii kun fọnfọn, o si jẹ eyi to n jẹ ka mọ iru eeyan ti a jẹ, to si n ran wa leti idanimọ wa, to n ran wa leti wi pe a ko gbọdọ jẹ ki aṣa wa lọ soko iparun. Eyi gan-an ni koko pataki ti a ṣakiyesi nibi, gbogbo awọn nnkan wọnyi lawọn ọmọ wa ti fi si ojuṣe nibi ti orin kikọ ati ti ariyanjiyanji to ti waye.

“Lati tun gbe aṣa wa dide yẹ ko jẹ ojuṣe gbogbo wa, nitori pe bi a ko ba ṣọra, aṣa lee lọ si oko iparun. Aṣa wa ni a gbagbọ ninu ẹ, aṣa wa ni aṣa wa, aṣa wa ni ede wa, a si tun fẹẹ sọ lẹẹkan sii lati ba Sẹnetọ, Ọmọọba Lanre Tẹjuoṣo yọ, ka si tun luu lọgọ ẹnu lati maa tẹsiwaju iru agbekalẹ to n gbe aṣa wa dide pada.


“Bakan naa la tun fẹẹ gba awọn ọmọ wa lamọran lati maa sọ ede wa, nitori pe ṣe la n gbe aṣa wa dide nipa bẹẹ, a si tun n ṣe ara wa ni anfaani to pọ rẹpẹtẹ, nitori pe bi a ba gba awọn ogo wẹẹrẹ wa laaye lati gbe aṣa wa dide, a maa wa mọ wi pe agbekalẹ wa loriṣiriṣi.

“Bi a gba tun gba awọn ọmọ wa laaye lati maa sọ ede wa, ti wọn si n ronu agbekalẹ tuntun nipa ede wa, bi awọn orileede bii China ṣe n ṣe, igba naa la maa to o mọ pe China lo n lewaju ninu awọn ileeṣẹ to n ṣe agbekalẹ nnkan. Eyi ṣee ṣe nitori pe wọn gba awọn ọmọ wọn laaye lati maa sọ ede wọn.


“Nigba ti a ba gba awọn ọmọ wa laaye lati maa sọ ede abinibi wa, oun kan ti a maa ṣakiyesi ni pe awọn naa n le ni ohun ti a n pe ni igboya lati ṣe ohunkohun, ko tun ni jẹ ka jiya, iyẹn bi a ba ni igboya nipa ohun ti a n ṣe.

“Mo fẹẹ sọ fun un yin pe inu mi dun lati wa nibi yii lonii, gẹgẹ bi gomina yin, mo si tun fẹẹ fi da a yin loju pe mo maa fi ijọba ipinlẹ Ogun silẹ ju ipo ti mo ba a lọ, abi ohun ti wọn gbe le wa lọwọ.”


Ọmọọba Lanre Tẹjuoṣo nigba toun naa n sọrọ, o sọ pe;
“Nigba ti mo kere, mi o ni iru anfaani ti awọn ọmọ yii ni, iyẹn lo fi ka mi lara wi pe emi naa ṣe iwọnba ti mo le ṣe, nipa awọn nnkan ti mi o ni anfaani ẹ.

“Kabiyesi nigba yẹn, wọn fẹran ilu Oyinbo lọpọlọpọ, ibẹ gan-an ni wọn bi mi si, iyẹn ni mi o fi raaye lati lọ si African Church Grammar School, ti emi naa ko ba ti di ogbontarigi ninu ede ati aṣa Yoruba. Diẹdiẹ ni mo gbọ ninu ede Ẹgba.


“Mo fi gbogbo ara dupẹ lọwọ gbogbo wa, paapaa awọn ọmọ mi, nitori pe gbogbo awọn akẹkọọ to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ọmọ mi ni wọn jẹ. Mo nigbagbọ wi pe ti ọdun to n bọ maa ju bayii lọ. Ilu Ẹgba, ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria ma maa lọ siwaju ni lagbara Ọlọrun. Ẹ ṣeun pupọ.”

Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo, Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba; Ọba Joseph Ọmọlade, Olubara tilu Ibara; Oloye Alaba Lawson, Iyalode Yoruba; Olori awọn oṣiṣẹ ijọba Ọmọwe Matthew Aigoro; Alabojuto fun ọrọ eto aṣa ati irin ajo afẹ, Dọkita Toyin Taiwo; Alaga ijọba ibilẹ Ariwa, Ọnarebu Abdulsalam Adebayọ Ayọtunde; Akọwe agba lẹka eto ẹkọ, Arabinrin Abọsẹde Ogunlẹyẹ ati Oloye Bọde Mustapha.

Awọn agba lẹka iṣẹ sọrọsọrọ ati igbohunsafẹfẹ bii Oloye Bunmi Ayelaagbe, Ayinla Ẹgba, Dapọ Ẹnlẹ Dadi, Ṣeun Adedeji ni wọn tukọ eto naa.
 
Ifọrọjagba ati ariyanjiyan lo waye laaarin awọn ile ẹkọ to yege de ibi aṣekagba naa. Lara wọn si ni ile ẹkọ Orile Iporo Community High School, Ọdeda; Abeokuta Girls Grammar School, Onikolobo Abẹokuta;  African Church Grammar School; Ọba Community High School; Pakoto High School ati Adeoye Lambo Memorial High School;

Awọn yooku ni Adenrele High School, Ifọ; Aṣero High School; Ẹgba Owode High School; Premier Grammar School ati Nawair-Ud-Deen Grammar School, Ọbantoko.


Nibi idije ariyanjiyan, ile ẹkọ Adeoye Lambo Memorial High School lo ṣe ipo kin-in-ni, nigba ti ile ẹkọ Ọba Community High School ṣe ipo keji, ti ile ẹkọ Orile Iporo Community High School si ṣe ipo kẹta.

Nibi idije orin kikọ, ile ẹkọ Adenrele High School lo ṣe ipo kin-in-ni, nigba ti ile ẹkọ Nawair-Ud-Deen ṣe ipo keji, ti ile ẹkọ Premier Grammar School si ṣe ipo kẹta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI