Alimi di Mutawali ilu Ilọrin, ni Ọṣinbajo, Ẹmir ilu Ilọrin atawọn eeyan nla-nla ba gbe oṣuba fun AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 21, 2022

Alimi di Mutawali ilu Ilọrin, ni Ọṣinbajo, Ẹmir ilu Ilọrin atawọn eeyan nla-nla ba gbe oṣuba fun AbdulRazaq


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan lawọn eeyan ṣi n royin ayẹyẹ ifinijoye ti Mutawali tilu Ilọrin, eyi ti wọn fi Ọmọwe Alimi AbdulRazaq jẹ.
 
Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi; Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo; Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, atawọn miran ni wọn wa nibẹ lọjọ naa.
 
Nibẹ ni Ẹmi tilu Ilọrin, Ọmọwe Sulu-Gambari, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo atawọn eeyan jankanjakan ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazahman AbdulRazaq fun awọn akanṣe iṣẹ manigbagbe to ti ṣe lati fi mu idagbasoke ba ipinlẹ naa, eyi to ti ṣe laaarin asiko to de ipo.
 
Nigba to n sọrọ Ọṣinbajo to jẹ ko di mimọ pe oun pẹlu Mutawali tuntun naa jọ lọ sileewe amofin ni sọ pe lati kekere lọkunrin naa ti jafafa, ati pe wọn ko ṣi eeyan yan sipo naa, o lẹni ti ipo naa tọ si ni wọn yan.

Bakan naa lọ sọ pe ọna ti baba rẹ to jẹ Mutawali akọkọ, Oloogbe AGF AbdulRazaq fi lelẹ loun naa tẹle.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI