Wọn ju gendekunrin marun-un sẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 21, 2022

Wọn ju gendekunrin marun-un sẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ilọrin


Ile ẹjọ giga t'ijọba apapọ to wa nilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti ju awọn gendekunrin marun-un kan ti a gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo lọ.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii la gbọ pe Onidajọ Muhammed Sani ju awọn eeyan naa sẹwọn lori ẹsun ọtọọtọ, eyi to nii ṣe pẹlu jibiti ori ayelujara ti ajọ to n gbogun iwa iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, EFCC fi kan wọn.

Awọn ọdaran naa ni Ọlọlade Ọlabisi lati ijọba ibilẹ Alimọṣọ l'Ekoo; Issa Adebayọ Ṣhahajudeen, ọmọ bibi ilu Ọffa nipinlẹ Kwara; Ṣẹgun Ajila Samson lati Alimọṣọ l'Ekoo; Babatunde Ọlarewaju Saheed lati ilu Ilọrin ati Abdulmatin Ọlawale Akibu lati ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ nipinlẹ Ọyọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI