Àwọn àlejò pàtàkì fẹ́ẹ́ wọ̀lú Abẹ́òkúta nítorí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Àjíkí Olú, gbajúmọ̀ pùròmótà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 1, 2022

Àwọn àlejò pàtàkì fẹ́ẹ́ wọ̀lú Abẹ́òkúta nítorí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Àjíkí Olú, gbajúmọ̀ pùròmótà


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja puromota nni, Oloye Arẹmu Bamgboye, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki Olu, eyi to fẹẹ waye niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ karun-un, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, oṣu kẹta, ọdun 2022 ti a wa yii la gbọ pe ayẹyẹ ọjọ ibi naa fẹẹ waye ninu gbọngan ayẹyẹ aṣa to wa ninu ọgba Olumọ, agbegbe Ikija, Abẹokuta.

Awọn ọtọkulu, eeyan jankan-jankan kaakiri orileede Naijiria ati lagbaye la gbọ pe wọn ti n mura silẹ lati wọ ilu Abẹokuta nitori ayẹyẹ ọjọ ibi naa.


Odu ni Oloye Ajiki Olu, ki i ṣaimọ f'oloko, paapaa lagboole amuludun ti tiata, ati olorin, to si ti gbe oriṣiriṣi orin ati fiimu agbelewo jade kaakiri.
 
Ayẹyẹ ọjọ ibi ti ọdun yii la gbọ pe o fẹẹ waye lara ọtọ, pẹlu bi wọn ti ṣe la ilana ati eto ọlọkan-o-jọkan kalẹ, eyi ti yoo jẹ ki ọjọ naa larinrin kọja afẹnuroyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI