Orí kó Ọba alayé n'ílùú Èkìtì yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé, wọ́n tún yìnbọn fún un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, March 1, 2022

Orí kó Ọba alayé n'ílùú Èkìtì yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé, wọ́n tún yìnbọn fún un


Awọn ajinigbe kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ wọn ni wọn ti yinbọn fun Ọba Abdul-Mumini Oriṣagbemi, Atah tiluu Ayede Ekiti, ipinlẹ Ekiti l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.

Iroyin to tẹ akọroyin AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe akoko ti Kabiyesi ọhun n pada si aafin rẹ la gbọ pe awọn ajinigbe naa dena de e, ti wọn si da ibọn bo mọto rẹ.

Oju ọna Isan Ekiti si Ayede Ekiti lawọn agbebọn naa ti wọn to mẹwaa ti dena de wọn, pẹlu erongba lati ji Kabiyesi gbe.

Ẹwẹ, lara awọn to fi iṣẹlẹ yii to wa leti sọ pe pẹlu agidi ni awakọ kabiyesi fi yọ bọrọ mọ wọn lọwọ, iyẹn ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Nibi ti awakọ naa ti n gbiyanju lati doola ẹmi oun pẹlu ti kabiyesi ni wọn sọ ibọn tawọn ajinigbe naa yin ba mọto wọn ti ba kabiyesi lẹsẹ.

AWIKONKO gbọ pe ki i ṣe akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ yii yoo maa waye loju ọna kan ṣoṣo yii, ti wọn si lagbegbe naa ti di itẹdo fun awọn ajinigbe.

Ọgbẹni Sunday Abutu to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti nigba to n fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe ilu Ijero ni ọba alaye naa ti n bọ, ko to di pe awọn ajinigbe naa sare jade ninu igbo, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ fun wọn.

Abutu sọ pe Kabiyesi ti wa ni ọsibitu, nibi to ti n gba itọju lọwọ, to si tun jẹ ko di mimọ pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ awọn to wa nidi iwa buruku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI