Àwọn ọmọ Nàìjíríà ló sọ pé kí Ọ̀ṣínbàjò jáde du ipò ààrẹ - ẹgbẹ́ alátìlẹyìn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 25, 2022

Àwọn ọmọ Nàìjíríà ló sọ pé kí Ọ̀ṣínbàjò jáde du ipò ààrẹ - ẹgbẹ́ alátìlẹyìn


Ẹgbẹ olóṣèlú kan ti wọn n ṣagbateru igbakeji ààrẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọ̀ṣínbàjò lati du ipo Ààrẹ orileede yii, l'ọjọ Ẹti, Furaidee, oni ti ṣe abẹwo si Ààrẹ tẹlẹri lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Michael Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, Okukenu kẹrin.

Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko ye wa pe igbimọ iṣakoso ẹlẹni mẹẹdogun ni ẹgbẹ naa gbe dide lati ṣabewo si Balogun ilu Owu, Oloye Ọbasanjọ ati Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Gbadebọ.

Oludamọran pataki fun Ààrẹ Buhari lori ọrọ oṣelu, Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, to lewaju igbimọ naa lakoko to n sọrọ ṣalaye pe awọn ololufẹ igbakeji aarẹ ni wọn n sọ pe ko jade lati du ipo aarẹ, to si l'awọn nilo atilẹyin awọn agbaagba lati ṣe adura fun un, ki ipo ọhun le ja mọ ọn lọwọ.

Fun bi ọpọlọpọ iṣẹju l'awọn igbimọ naa fi wọle ipade ikọkọ pẹlu Oloye Ọbasanjọ, ti ko si sẹni to le sọ pato ohun ti baba naa ba wọn sọ, ṣugbọn ti igbagbọ wa wi pe amọran nla lo fun wọn.

Lẹyin eyi ni wọn lọ si aafin Alake Ẹgba, nibi ti Ọba Gbadebọ ti gba wọn lalejo, to si gbadura wi pe gbogbo ohun ti wọn n beere fun ni Olodumare yoo ṣe fun wọn.

Titi di asiko ti a ṣakojopo iroyin yii tan, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ko tii fi erongba rẹ han sita gbangba wí pé òun fẹẹ jade du ipo aarẹ, ṣugbọn ti wọn ni abẹlẹ lo ti n ṣiṣẹ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI