Ẹgbẹ àwọn onímọ́tò àti kẹ̀kẹ márúwá ṣèlérí ìdìbò ẹlẹ́ẹ̀kejì fún AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 6, 2022

Ẹgbẹ àwọn onímọ́tò àti kẹ̀kẹ márúwá ṣèlérí ìdìbò ẹlẹ́ẹ̀kejì fún AbdulRazaq


Ẹgbẹ awọn onimọto NURTW ati awọn to n wa kẹkẹ Maruwa, TOAN nipinlẹ Kwara ti sọ pe ko si ẹni meji tawọn yoo fun ni ibo wọn si ipo gomina lọdun 2023 to yatọ si AbdulRahman AbdulRazaq.

Wọn ni awọn ipa rere idagbasoke to n ko latigba to ti wa ni iṣakoso lo n jọ awọn loju, ati pe bo ṣe gba alaafia, iṣọkan ati ifẹ laaye nipinlẹ naa jẹ eyi to n mu ori wu.

Nigba ti wọn n sọrọ, awọn aṣoju ẹgbẹ mejeeji yii, Sulyman Mustapha, Afolabi Sulyman ati Ọmọtọṣhọ Abduquadir, ṣapejuwe AbdulRazaq gẹgẹ bi gomina ọrẹ araalu, nitori to n tẹti gbọ ọrọ awọn eeyan lati mu inu wọn dun.

Wọn ni ọpọ igba ni mọto ati kẹkẹ Maruwa wọn n bajẹ, eyi to mu ki wọn maa na owo ribiribi lee lori fun atunṣe, ṣugbọn latigba ti AbdulRazaq ti bẹrẹ iṣẹ atunṣe opopona kaakiri lawọn ko ti ri mọto ati kẹkẹ Maruwa wọn gẹgẹ bi agbana mọ.

Nibẹ ni wọn ti wa jẹ ko di mimọ pe pẹlu gbogbo ipa rere idagbasoke ti AbdulRazaq n ko yii, paapaa lori atunṣe opopona Gaa-Akanbi-Agbabiakan, o ti di dandan lati tun dibo fun lẹẹkeji, ko le tubọ pari awọn iṣẹ to dawọ le.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI