Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe iku Grand Khalifah Sheikh Abdullahi Yusuf (Al-Argbaji) gẹgẹ bi adanu nla fun asiko yii.
Bakan baa lo ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ Zumuratul-Mumeen kaakiri agbaye kẹdun iku agba olori ẹsin naa, ẹni to jade laye laipẹ yii.
O tẹsiwaju pe ohun to dun oun lọkan gidigidi ni bi aṣaaju ninu ẹsin, ti awọn eeyan n lo awokọṣe rẹ fi dagba, paapaa niluu Ilọrin ti jade laye.
O wa gbadura ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment