Emi ati Sẹnetọ Ọbadara la maa sọ ẹni ti yoo ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lọdun 2023 - Sẹnetọ Lanre Tẹjuoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 17, 2022

Emi ati Sẹnetọ Ọbadara la maa sọ ẹni ti yoo ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lọdun 2023 - Sẹnetọ Lanre Tẹjuoṣo


Sẹnetọ to ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nigba kan ri, Sẹnetọ Ọlanrewaju Tẹjuoṣo ti sọ pe oun pẹlu ẹni toun gba ipo naa lọwọ ẹ, Sẹnetọ Gbenga Ọbadara lawọn yoo jọ mọ ẹni ti yoo tun pada sipo naa lọdun 2023.
 
O sọ pe lẹyin tawọn ba ti jọ jiroro, lawọn yoo to fi ẹnu ko lati mọ ẹni ti wọn yoo fa kalẹ lati jade du ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin agba orileede yii, iyẹn Sẹnetọ ti yoo ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Ogun Central.
 
Nibi aṣekagba eto idije ariyanjiyan to waye laaarin awọn akẹkọọ ile-ẹkọ to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ẹlẹẹkẹrin iru ẹ ti Sẹnetọ Lanre Tẹjuoṣo maa n ṣagbatẹru ẹ lọdọọdun, eyi to waye ninu gbọngan ayẹyẹ ti OOPL to wa nilu Abẹokuta lo ti sọrọ naa jade.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye siwaju pe;
"Mo fẹẹ ki ẹni to kọ mi bi wọn ṣe n ṣe Sẹnetọ, iyẹn Sẹnetọ Gbenga Ọbadara daadaa, wi pe wọn ku iṣẹ. Mo fẹẹ jẹ ki ẹ mọ pe laaarin emi ati wọn, awa la maa sọ ẹni to tun maa pada sipo Sẹnetọ laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun. A jọ maa jokoo sọrọ yii ni. Ẹni ti a ba si sọ lo maa pada wọle."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI