Iku Adegoke: Ẹ gba mi o! Wọn fẹẹ fi oṣelu ba t'emi jẹ ni o - Guru Maharaji Ji pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ





Monday, March 21, 2022

Iku Adegoke: Ẹ gba mi o! Wọn fẹẹ fi oṣelu ba t'emi jẹ ni o - Guru Maharaji Ji pariwo sita


Alaṣẹ ati olori ijọ mọlẹbi kan, iyẹn One Love Family, Satguru Maharaj Ji ti pariwo sita wi pe oun ko mọ nnkankan nipa iku Timothy Adegoke, ẹni ti wọn pa si otẹẹli Hilton laipẹ yii, to si ni oṣelu ni wọn fẹ maa fi darukọ oun mọ ẹjọ naa, nitori pe digbin lọkan oun mọ si iwa naa.
 
Bakan naa lo sọ pe oun ko ni ajọṣepọ kankan pẹlu Oloye Rahman Adedoyin, ẹni to jẹ ọkan gboogi lara awọn afurasi to ṣeku pa Adegoke.
 
Maharaj Ji lo pariwo yii sita l'ọjọ Aiku, Sannde ana lakoko to n bawọn akọroyin sọrọ ninu ṣọọṣi ẹ nibi ipade awọn oniroyin to pe.
 
Bẹ o ba gbagbe, Adegoke, ẹni to jẹ akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa nilu Ile-Ifẹ ni wọn pa danu si otẹẹli Adedoyin lakoko to lọ fun idanwo.
 
Maharaj Ji wa sọ pe ohun ti ko dara ni lati maa sọ pe oun mọ nnkan nipa bi wọn se ṣeku pa akẹkọọ, to si n jẹ ko ye gbogbo aye wi pe ọrọ oṣelu ni wọn fẹẹ fi sọ pe oun naa mọ nipa ẹ.
 
Siwaju si i lo sọ pe igba akọkọ toun yoo pade Adedoyin laye oun ni ọjọ to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun, ti wọn si fi iwe pe oun lati wa yẹ wọn si.
 
O ni idi pataki toun fi lọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni pe Adedoyin wa lara awọn to n du ipo Ọọni Ile Ifẹ lọdun diẹ sẹyin. Bakan naa lo tun sọ pe lara idi pataki toun fi lọ sibẹ ni pe lati tuu ninu nigba to padanu ipo Ọọni

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI