Yeketi, kọmiṣanna tẹlẹ ni Kwara fẹgbẹ PDP silẹ, o loun ti ba APC lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 21, 2022

Yeketi, kọmiṣanna tẹlẹ ni Kwara fẹgbẹ PDP silẹ, o loun ti ba APC lọ


Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara, Alaaji Ayinla Musa Yeketi, ẹni to ti figba kan ri jẹ kọmiṣanna nipinlẹ naa ti kede sita wi pe oun ti ba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọ.
 
Yeketi, ẹni to tun ti figba kan ri jẹ alaga igbimọ ile ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kwara lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii pe oun ko le tẹsiwaju lati maa ba wọn ṣe ẹgbẹ PDP mọ, to si ni inu ẹgbẹ APC loun ti ri ọjọ iwaju rere fawọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI