Jimi Lawal ṣabẹwo s'awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 26, 2022

Jimi Lawal ṣabẹwo s'awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP l'Abẹokuta


Oludije sipo gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọtunba Jimil Adebisi Lawal lo ti ṣe abẹwo si awọn oloye ẹgbẹ oṣelu naa lati fi erongba rẹ han si wọn.

Olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni Jimi Lawal ti lọ ṣe abẹwo ọhun lonii, ọjọ Abamẹta, Satide.

Alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Sikirulai Ogundele at'awọn oloye ẹgbẹ naa lo gba Ọtunba Jimi Lawal pẹlu ikọ akọwọrin ẹ lalejo, nibi ti wọn ti fi ọkan rẹ balẹ wi pe digbi l'awọn wa lẹyin ẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI