Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti fidi ileri rẹ mulẹ fun gbogbo awọn ọdọ lẹka ere idaraya wi pe oun ko nii dawọ duro lati maa ṣe iranwọ to ba yẹ nipa gbigbe ere idaraya larugẹ, ko si di ohun tawọn eeyan, paapaa awọn ọdọ lawujọ n ri gẹgẹ bi iṣẹ oojọ.
AbdulRazaq lo fidi ọrọ yii mulẹ l'Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja yii lakoko ti wọn n fi ẹgbẹ awọn ololufẹ ere idaraya, iyẹn Supporters Club fun ikọ Super Eagles lelẹ.
Nibẹ lo tun ti ṣe ileri wi pe g gbogbo igbesẹ loun yoo gbe lati rii daju pe papa iṣere ipinlẹ naa, ati awọn ohun elo gbogbo to wa nibẹ ba ti agbaye lọna igbalode mu, fun irọrun awọn ọdọ.
Siwaju sii, iyẹn nibi to ti n gbalejo ẹgbẹ awọn alatilẹyin ere idaraya ti a mọ si Supporters Club fun ikọ Super Eagles yii, eyi ti Ọmọọba Vincent Okumagba jẹ Aarẹ wọn lapapọ nilegbe gomina to wa nilu Ilọrin, ipinlẹ naa, AbdulRazaq sọ pe lara awọn nnkan to jẹ ijọba oun logun ni lati rii pe awọn ọdọ n ṣe ohun kan ti yoo mu inu wọn dun.
"A n sa gbogbo ipa wa lati rii pe idagbasoke wa fun ẹka ere idaraya nipinlẹ yii. A maa ṣe awọn atunṣe rere si papa iṣere tilu Ilọrin ati tilu Ọffa, ki wọn le maa fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu eyi to ku lagbaye, ti wọn yoo si di lilo fun idije agbaye to ba fẹẹ waye.
"A ṣi ma maa tẹsiwaju lati maa ṣe iranlọwọ kikun to ba yẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United FC, ti a si tun n foju sọna fun ọjọ ti a maa gba ikọ Super Eagles funra wọn lalejo."
No comments:
Post a Comment