Nitori wahala ijaabu lagbegbe Ijgabo, awọn igbimọ jokoo ipade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 17, 2022

Nitori wahala ijaabu lagbegbe Ijgabo, awọn igbimọ jokoo ipade


Igbimọ ẹlẹni meje kan tijọba ipinlẹ Kwara lati ri si wahala to n waye lori ọrọ ijaabu nilu Ijagbo, ipinlẹ naa ti jokoo ipade lati wa ọna bi wahala naa yoo ti pari.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wahala naa dide nile ẹkọ girama ti Oyun, iyẹn Oyun Baptist High School to wa nilu Ijagbo, ipinlẹ naa.
 
Awọn igbimọ yii la gbọ pe lọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ti bẹrẹ ipade niluu Ilọrin, lati jiroro lori bi wahala naa yoo ṣe dopin titilai.
 
Nibẹ ni alaga igbimọ naa, Ọmọwe Ṣhehu Ọmọniyi ti ṣalaye pe igbimọ naa kii ṣe lati dunkoko mọ ẹnikẹni, bi ko ṣe lati wa ọna abayọ si wahala to n fojoojumọ dide, ki iru awọn wahala naa ma ba a tun maa dide mọ.
 
Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni akọwe agba fun ẹgbẹ ọmọ Ijagbo, iyẹn Ijagbo Descendants Progressive Union, Ọgbẹni Emmanuel Adebayọ Fatọla;Pasitọ Modupẹ Ọrẹyẹmi Agboọla; Ọmọwe Saudat Baki; Alaaji Ibrahim Zubair Danmaigoro; Ajihinrere Timothy Akangbe; ati Ọgbẹni Iṣhọla Olofere, toun jẹ akọwe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI