Wọn ti opopona Adeta si Oloje pa ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 17, 2022

Wọn ti opopona Adeta si Oloje pa ni Kwara


Ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Road Traffic Management Authority ti kede sita wi pe ki gbogbo awọn awakọ patapata wa awọn ọna miran ti yoo rọrun fun wọn dipo layipo to so awọn agbegbe kan pọ.

Wọn ni ijọba ti kede titi layipo Adeta pa fun ọjọ mẹrinla, iyẹn ọsẹ meji gbako fun atunṣe, bẹrẹ lati oni, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii.
 
Layipo naa la gbọ pe o so agbegbe Yebumot-Al-Hikmah University, Adeta ati Oloje papọ.

Wọn ni ki gbogbo awọn awakọ to n bọ lati Kano, Yebunot/Al-Hikmah University bẹrẹ sii gba oju ọna Aromaradu, Socrates, ati Benin ni Adewọle.

Bẹẹ ni wọn sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ to n boju to igbokegbodo ọkọ yoo wa nitosi lati rii pe wọn n bojuto bi ọkọ yoo ṣe maa lọ.
 
Alakoso ileeṣẹ naa, Alaaji Yẹkeen Babatunde Bello wa gba gbogbo araalu lamọran lati rii daju pe wọn n fọwọsowọpọ lati rii pe ọkọ n lọ geerege.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI