Ọkan lara awọn ipinnu ati erongba mi ni lati pese aadọta omi ẹrọ igbalode fawọn araalu - Ayọ Adeṣina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 18, 2022

Ọkan lara awọn ipinnu ati erongba mi ni lati pese aadọta omi ẹrọ igbalode fawọn araalu - Ayọ Adeṣina


Ọkan lara awọn oludije sipo aṣoju-ṣofin l'ẹkun Guusu Abẹokuta ninu idibo ọdún 2019, Ọnarebu Ayọ Adeṣina ti sọ pé ẹdun ọkan lo máa n jẹ foun l'awọn ìgbà toun ba n ri akitiyan awọn araalu lati wa omi ti wọn yoo mu, pàápàá eyi ti wọn yóò lo, tó sì ni lara àwọn erongba oun ni láti pese omi fún gbogbo wọn.

Adeṣina, ẹni tó jáde du ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, ṣugbọn to padanu sọwọ oludije lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ìyẹn Ọnarebu Lanre Ẹdun lo sọ eyi di mimọ lori ikanni ayelujara ti Fesibuuku laipẹ yii.

Ọkunrin naa, nigba to n da si ọrọ kan nipa iṣoro ti awọn araalu n koju nipinlẹ Ogun, paapaa niluu Abẹokuta labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun, o ni gbogbo awọn iṣoro yii loun ti ri tipẹ, idi pataki toun fi jade lati du ipo, ko le raaye ṣe awọn iṣẹ to fẹẹ ṣe fun araalu.

Siwaju sii, ninu ọrọ rẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn ipinnu ati erongba oun ni lati pese omi si agbegbe ti ko din ni aadọta nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta toun fẹẹ ṣoju, ko le din wahala omi pipọn ku.

Ninu ọrọ rẹ, o tẹsiwaju pe:
"Ọkan lara awọn ipinnu ati afojusun mi gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin nigba ti mo jade du ipo ni lati ṣe omi ẹrọ igbalode ti ko din ni aadọta kaakiri ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, iyẹn bi wọn ba fi ibo gbe mi wọle.

"Maa ri i daju pe mo ṣe ẹyọkan, o kere ju ni ẹẹkan loṣu ni gbogbo akoko ti maa lo ni ọfiisi gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin.

"Mo mọ bo ṣe le koko to. Idi ree ti mo fi fẹẹ jẹ ko jẹ akanṣe iṣẹ ti yoo jẹ ontẹ mi gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin, ti mo si polongo nipa rẹ kọja afẹnuroyin.

"Ṣugbọn ṣa, awọn oludibo ni awọn oloṣelu miran ti wọn fẹran, ti wọn si fi han nipa ibo wọn, iyẹn si dara. Nipa ireti, ọkan lara awọn ti wọn dibo fun yoo wo wahala ati idaamu wọn lati ṣe iranlọwọ fun wọn."

Bo tilẹ jẹ Ọnarebu Ayọ Adeṣina ko tii sọ èròngbà rẹ lati tun jade du ipo naa lọdun 2023, ṣugbọn pupọ lara awọn ololufẹ ọkunrin naa, ti wọn nigbagbọ ninu ohun to le ṣe nipa iwa ọmọluwabi ati ẹyinju aanu rẹ ni wọn n sọ pe ko jade pada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI