Tinubu kìí ṣe olùgbàlà Nàìjíríà - Wòlíì Iyunade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 20, 2022

Tinubu kìí ṣe olùgbàlà Nàìjíríà - Wòlíì Iyunade


Aarẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Pentecostal Sanctuary Bible Ministry, to wa lagbegbe Odo-Ẹgbọ niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun, Wolii Sunday Dare Iyunade ti sọ pe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC kii ṣe ẹni ti yoo gba orileede yii la kuro ninu iṣoro to n koju.

Wolii Iyunade sọ pe Ọlọrun nikan ni olugbala, ti awọn eeyan gbọdọ maa ke pe lati yan adari gidi ti yoo tukọ orileede yii de ilẹ ileri, ṣugbọn to sọ pe ẹni tọpọ awọn eeyan n wo gẹgẹ bi olugbala kii ṣe bẹẹ rara, nitori pe ẹlẹran ara eniyan ni.

Nibi ipade awọn akọroyin ti Wolii Iyunade ṣe fun ti ayẹyẹ ọdun kẹrindinlọgbọn ti wọn da ijọ naa silẹ, ati ayẹyẹ ogun ọdun ti wọn bẹrẹ ipagọ wọn to waye laipẹ yii ni Wolii Iyunade ti sọ oriṣiriṣi asọtẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ lọdun yii ati awọn ọdun to n bọ, paapaa nipa idibo ọdun 2023.

Nigba to n sọrọ, o sọ pe 
“Nnkan nla kan yoo ṣẹlẹ, ti yoo mi orileede yii titi. Mo ri iji nla lile ti oṣelu kan to la orileede yii kọja, iji naa yoo jẹ atunṣe fun orileede yii. Awọn ọmọ Naijiria n palẹmọ gidi fun idibo 2023, ko nii si idibo ti yoo lọ pẹlu alaafia, ayafi bi awọn to wa nipo lakoko yii ba kuro.

“Gbigbe eto idibo kalẹ kan jẹ lati na anadanu owo ti ko si, fun idi eyi, a nilo adura gidigidi. Aisi eto aabo jẹ ohun elo lọwọ awọn oloṣelu kan, a nilo idasi atoke wa.

“A nilo lati gbadura wi pe ki Ọlọrun paarọ awọn olori ti wọn n dari wa lorileede yii, nitori pe bi wọn ba si n tẹsiwaju, ipinu wọn ko nii mu idagbasoke ba orileede yii. Ọlọrun yoo fi iya to tọ jẹ gbogbo awọn to n fa orileede yii pada sẹyin, ti wọn si n ba eto ọrọ aje orileede yii jẹ.

“Ẹni ti awọn eeyan n wo gẹgẹ bi olugbala, kii ṣe olugbala rara, Ọlọrun nikan ni olugbala to yẹ ka ke pe. Awọn Iwọ-Oorun orileede yii ni wọn lẹnu nipa fifi olori jẹ lorileede yii, ṣugbọn ti wọn farabalẹ lati gba ẹtọ won, bi awọn naa ṣe maa de ipo agbara ni wọn n wa.

“Orileede Naijiria ṣi maa padanu awọn alagbara ati akikanju oloṣelu. Wọn ti fi aami iku si wọn lara, a nilo lati gbadura fun wọn.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI