Ajinde: Oloye Aderinokun b'awọn Kristẹni yọ, o tun gba wọn lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 16, 2022

Ajinde: Oloye Aderinokun b'awọn Kristẹni yọ, o tun gba wọn lamọran


Akinruyiwa tilu Owu, Abẹokuta, Oloye Olumide Aderinokun ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin Kristẹni kaakiri agbaye, paapaa laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun yọ lori ayẹyẹ ọdun Ajinde Jesu to wọle wẹrẹ yii.

Oloye Aderinokun ninu atẹjade to n fi ki gbogbo awọn to n ṣajọyọ iku ati ajinde Jesu, eyi to gbe jade laipẹ yii lo ti sọ pe ki awọn Krsitẹni ma ṣe jẹ ki iku Jesu lori igi agbelebu lọ lasan.

Aderinokun, eni to n foju sọna lati dije du ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun naa sọ pe ki wọn lo akoko yii lati fi maa gbadura fun orileede Naijiria, ko le ri bi wọn ṣe n fẹ.

Nibẹ lo tun ti gba wọn lamọran lati rii pe wọn n gbe ifẹ, iṣọkan larugẹ lai lo ẹlẹyamẹya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI