O pari, ile-ẹjọ paṣẹ pe ki aga aṣoju-ṣofin Saheed Popoọla ṣofo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 16, 2022

O pari, ile-ẹjọ paṣẹ pe ki aga aṣoju-ṣofin Saheed Popoọla ṣofo


Ile ẹjọ giga tipinlẹ Kwara, eyi to wa niluu Ilọrin ti paṣẹ pe ki aaye Ọnarebu Saheed Popoọla to n ṣoju agbegbe Ojomu/Balogun nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ṣofo, lẹyin to kuro lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to gbe e wọle lọ sinu ẹgbẹ oṣelu miran, iyẹn Social Democratic Party, SDP.

Ṣaaju akoko yii ni ile ẹjọ naa labẹ Onidajọ I.A Yusuf ti kọkọ paṣẹ lati da abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa lọwọ kọ fun igba diẹ lati kede aga Ọnarebu Popoọla wi pe o ṣofo.

Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii la gbọ pe ile ẹjọ naa paṣẹ pe ki aga naa ṣofo niwọn igba ti Ọnarebu naa ti sọ pe ẹgbẹ to gbe oun wọle ti su oun.

Bẹ o ba gbagbe, ṣaaju akoko yii ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ti fi lẹta kan ranṣẹ si ajọ INEC to n ṣakoso eto idibo wi pe aga Ọnarebu Popoọla ti ṣofo niwọn igba ti ẹgbẹ naa ko ti pin, ati pe ẹni to di ipo naa mu tẹlẹ ti fi ẹgbẹ silẹ, ni ibamu pẹlu iwe ofin orileede yii ti ọdun 1999, abala 109 (1)(g).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI