Ẹ ku ojulọna, mo fẹẹ kede ipinnu mi lati jade du ipo Aarẹ Naijiria - Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 28, 2022

Ẹ ku ojulọna, mo fẹẹ kede ipinnu mi lati jade du ipo Aarẹ Naijiria - Amosun


Gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Aṣofin Ibikunle Amosun ti sọ pe oun ti ṣetan lati kede ipinnu oun lati jade du ipo Aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alll Progressives Congress, APC.
 
Amosun, ẹni to n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin orileede yii to wa niluu Abuja lọwọlọwọ lo sọ eyi di mimọ loju opo ti fesibuuku rẹ nirọlẹ ana, Ọjọru, Wẹsidee, to si ni ki gbogbo awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ oun maa gbaradi fun ikede oun.
 
Siwaju si i nigba to n sọrọ, Amosun sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun 2022 ti a wa yii loun yoo kede ipinnu oun naa jade sita.
 
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe gbagede Shehu Musa Yar’Adua Centre, CBD, to wa niluu Abuja, FCT loun yoo ti kede naa fun gbogbo aye.
 
O wa n pe gbogbo eeyan, paapaa akẹgbẹ rẹ nile igbimọ aṣofin lati wa nibẹ, ki wọn le ri, ki wọn si gbọ awọn erongba rere oun fun orileede Naijiria lapapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI