Awọn olukọ SUBEB to din ni ẹgbẹrun meji (1,920) ni wọn ti bẹrẹ idanilẹkọọ ọlọsẹ meji gbako ti ijọba gbe kalẹ labẹ akoso ileṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ, iyẹn SUBEB.
Nibẹ ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi idunnu rẹ han si bi awọn olukọ naa ṣe mu ọrọ idanilẹkọọ ọhun lokunkundun, ti wọn ko si ta a nu.
Lojuna lati jẹ ki eto ẹkọ ipinlẹ Kwara ba ti igbalode agbaye mu, ati lati mọ bi ikẹkọọ yoo ṣe maa lọ lori ayelujara, lo mu ki ijọba Kwara gbe eto kan ti wọn pe ni KwaraLEARN (Leading Education Achievement and Reform Now) kalẹ, fun gbogbo olukọ ati akẹkọọ patapata lati jẹ rẹ.
Kaakiri gbogbo ile-ẹkọ ijọba to wa n'ipinlẹ naa la gbọ pe anfaani yii yoo de, ti wọn yoo si jẹ ki awọn akẹkọọ le maa figagbaga pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lagbaye, paapaa nipa imọ ẹrọ ti tẹkinọlọji.
Awọn ile-ẹkọ to wa l'awọn ijọba ibilẹ bii Baruten, Offa, Ilọrin West, ati Ilọrin East ni wọn ti bẹrẹ eto yii, nigba ti awọn ijọba ibilẹ yooku naa yoo jẹ anfaani tiwọn nigba ti ipele akọkọ ba pari, gẹgẹ bi aṣe gbọ.
No comments:
Post a Comment