Ẹ w'oju bola-bola to ji ẹru ile onile ko n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 7, 2022

Ẹ w'oju bola-bola to ji ẹru ile onile ko n'Ilọrin


Ṣikun bayii lọwọ awọn ẹṣọ aabo-ara-ẹni-l'aabo-ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi tẹ gbajugbaja bola-bola, iyẹn awọn to n ṣa irin kaakiri agbegbe, Akilu Lawali pẹlu ẹri ile onile to lọ ji ko.
 
Gbogbo ẹru inu ile idana ile kan to wa lagbegbe Ayekalẹ nitosi Ogidi niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara la gbọ pe Akilu lọ ji ko, to si n ko o salọ, ko to di pe aṣiri rẹ tu sita.
 
Babawale Zaid Afọlabi to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nigba to n f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe nnkan bi agogo meje alẹ, ọjọ kẹrin, oṣu yii ni Akali lọ si le naa lati lọ ji ẹru ko ni ile idana wọn.
 
Babawale sọ pe Akali ninu ọrọ rẹ sọ pe ṣe loun ra awọn ẹru naa.
 
Akali lawọn kan lo da oun duro pe ṣe oun maa ra awọn ẹru naa, toun si sọ pe bẹẹni, o ni ẹgbẹrun mẹwaa naira ni wọn n beere lọwọ oun, toun si sọ pe agbara oun ko ka a.
 
Nigba to sọ pe oun fẹ maa lọ lo ṣalaye pe ṣe ni wọn di oun mu, ti wọn si bẹrẹ sii lu oun, ko to di pe gbogbo ẹgbẹrun meje naira to wa lapo ounj ni wọn gba, ko to di pe wọn salọ.
 
O nibi toun ti n sunkun ni ẹnikan ti gbe mọto de, to si beere ohun to ṣẹlẹ. O loun ko ti i ṣalaye tan ti awọn kan ti de, ti wọn si tun bẹrẹ sii lu oun, ki wọn to lọ fa oun le awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI