Gomina Nyesom Wike, ti ipinlẹ Rivers ti tu aṣiri nla nipa Aarẹ ile igbimọ aṣofin orileede yii tẹlẹri, Sẹnetọ Bukọla Saraki wi pe fọọmu meji ọtọọtọ lo ti gba.
Wike lo tu aṣiri yii lakoko to ṣabẹwo si ipinlẹ Gombe, nibi to ti lọ fi erongba rẹ lati dije du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP han fawọn eeyan.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun nikan loun gba fọọmu kan ṣoṣo laaarin awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ naa.
O ni pupọ awọn ti wọn jọ fẹẹ du ipo Aarẹ lo jẹ pe fọọmu meji ọtọọtọ ni wọn gba nitori bi ipo naa ko ba bọ si i fun wọn.
Wike rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn oloye ẹgbẹ PDP lati gbaruku ti oun fun ipo naa, ki wọn si le jọ gbe orileede yii larugẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Emi ko gba fọọmu miran. Awọn kan fẹẹ di aarẹ, ṣugbọn wọn tun gba fọọmu lati du ipo sẹnetọ, iyẹn bi ipo aarẹ ko ba bọ si i fun wọn. Emi ko gba fọọmu miran nitori pe mo ti gbaradi fun un.
"Awọn ti wọn ko gbaradi ni wọn n sọ pe ki wọn tọju fọọmu miran fun awọn nitori ti ipo naa ko ba ja mọ wọn lọwọ. Emi ko le ṣe bẹẹ ni temi, eyi nikan ni maa gba."
No comments:
Post a Comment