Ẹni to tọ n'ijọba apapọ fi ṣe ọgagun ileeṣẹ panapana lorileede yii - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 28, 2022

Ẹni to tọ n'ijọba apapọ fi ṣe ọgagun ileeṣẹ panapana lorileede yii - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba rabandẹ fun ijọba apapọ lori bi wọn ṣe yan Onimọ-ẹrọ  Jaji Olola Abdulganiyu (MNSE), gẹgẹ bi ọgagun patapata fun ileeṣẹ panapana lorileede Naijiria, to si ni ẹni to tọ ni wọn yan sipo.
 
AbdulRazaq sọrọ yii ni kete tijọba apapọ kede Onimọ-ẹrọ Jaji gẹgẹ bi olori pata fun ileeṣẹ panapana laipẹ yii.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, AbdulRazaq sọ pe Jaji, ọmọ bibi ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara naa ti ṣiṣẹ takuntakun lati ko ara rẹ ni ijanu, to si ti fi gbogbo ara ṣiṣẹ lati ri i daju pe oun gun oke agba nidi iṣẹ to yan laayo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI