Ileeṣẹ ọlọpaa Abuja fẹẹ le gbogbo awọn to n ṣa irin kaakiri igboro danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 15, 2022

Ileeṣẹ ọlọpaa Abuja fẹẹ le gbogbo awọn to n ṣa irin kaakiri igboro danu


Ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja to jẹ olu-ilu orileede Naijiria ti sọ pe asiko ti to fun gbogbo awọn ṣarinṣarin, iyẹn awọn bola-bola lati fi ilu naa silẹ, nitori pe ko saaye kankan fun mọ nibẹ, ati pe akoko ti to lati fọ ilu naa mọ ni tonitoni.
 
DCP Ben Igwe to jẹ igbakeji ọga ọlọpaa ilu Abuja lo sọ eyi di mimọ lakoko to n f'oju gbogbo awọn ṣarinṣarin tọwọ tẹ han f'awọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, to si lawọn ko le gba wọn laaye mọ.
 
Mejidinlaadọrun-un la gbọ pe ọwọ ti tẹ ninu awọn ṣarinṣarin naa, ti a gbọ pe pupọ ninu wọn ni wọn n lo anfaani iṣẹ ọhun lati ja awọn araalu lole, eyi to ni ko bojumu to.
 
DCP Igwe sọ pe ilu Abuja ki i ṣe gbogbo eeyan, bi ko ṣe awọn to n hu iwa ọmọluabi, paapaa awọn eeyan pataki lawujọ, to si lawọn ti ṣetan lati da onikaluku wọn pada si ilu ti wọn ti wa lẹyin iwadii.
 
O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn ajoji ti n wọ ilu Abuja wa lati ṣiṣẹ ibi, eyi to lawọn ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe ọwọ tẹ awọn ajoji naa ti wọn gbero lati ṣiṣẹ ibi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI