Ṣikun bayii lọwọ ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba, iyẹn Amọtẹkun tẹ awọn ogbontarigi adigunjale kan n'ipinlẹ Ondo, iyẹn awọn ti wọn sọ pe wọn n da alaafia ipinlẹ naa laamu.
Awọn meji kan ti wọn pe inagijẹ wọn ni Anini ati Osunbor naa wa lara awọn ti ọwọ tẹ, ti wọn si ti f'oju wọn han f'awọn akọroyin ipinlẹ ọhun.
Timilẹhin Fẹmi, ọmọ ọdun mẹtala ti ọpọ mọ si Anini; Sunday Ojo, ọmọ ọdun mẹrindinlogun toun n jẹ Oyenusi; ati Matti Lowe, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti wọn tun mọ si Osunbor lọwọ palaba wọn segi, ti a si gbọ pe o ti pẹ ti wọn ti n wa wọn.
Ogbologbo adigunjale ni wọn pe awọn mẹtẹẹta ti a si gbọ pe ko din ni ogoji idigunjale ti wọn ti kopa ninu ẹ kaakiri ipinlẹ Ondo ko to di pe omi pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ wọn.
Nigba ti wọn n jẹwọ ni olu ileeṣẹ Amọtẹkun to wa lagbegbe Alagbaka nilu Akurẹ, Fẹmi ti awọn eeyan tun mọ si Anini sọ pe ọmọ ọdun mejila loun wa t'oun ti n jale, ati pe mama oun lo maa n ro oun lagbara ki ọwọ ma ba a tẹ oun.
O ni ori orule loun maa n tọju ibọn oun si, tabi koun lọ fi pamọ s'ọdọ Babalawo to n ṣoogun fun wọn. Bẹẹ lo sọ pe Babalawo to n ṣiṣẹ fun won l'awọn maa n ko gbogbo ẹru ti wọn ba jigbe lati ta a.
Anini tẹsiwaju pe idigunjale to to mẹrindinlaadọta loun ti kopa nibẹ.
Ninu ọrọ ti ẹ, Ojo ti wọn n pe ni Oyenusi jẹ ko di mimọ pe oun ko le ka iye igba toun ti kopa ninu ole jija, ati pe awọn araadugbo ni wọn sọ oun lorukọ Oyenusi naa.
Yatọ si awọn mẹta yii, awọn miran ti wọn tun f'oju wọn han ni mama Ojo, Arabinrin Iyabọ Fẹmi; Kẹhinde Ayọdele to jẹ babalawo wọn ati iya Kẹhinde toun naa tun n ṣe iranwọ fun wọn.
Olori Amọrẹkun nipinlẹ naa, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, nigba to n sọrọ ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ wi pe awọn tun gburo ẹnikeji ti wọn n pe ni Oyenusi, ati pe ọmọ ọdun mẹtala ni, to tun sọ pe mama oun lo n ṣoogun f'oun.
No comments:
Post a Comment